Close Menu
  • HOME
  • NEWS
  • POLITICS
  • SPORTS
  • ENTERTAINMENTS
  • EDUCATION
  • CRIMES
  • BUSINESS
  • OPINIONS

Subscribe to Updates

Get the latest creative news from FooBar about art, design and business.

What's Hot

Ib’North Bye-Election: Gbolarumi Congratulates Folajimi Oyekunle On Election victory

August 22, 2025

Watch: Makinde’s Administration Drives Oyo PTS Major Transformation to International Standard [VIDEO]

August 22, 2025

PHOTOS: Fire Engulfs Residential Building In Iseyin

August 22, 2025
Facebook X (Twitter) Instagram
  • HOME
  • ABOUT US
  • CONTACT US
Facebook X (Twitter) Instagram Pinterest VKontakte
Heritage EchoHeritage Echo
  • HOME
  • NEWS
  • POLITICS
  • SPORTS
  • ENTERTAINMENTS
  • EDUCATION
  • CRIMES
  • BUSINESS
  • OPINIONS
Heritage EchoHeritage Echo
Home » Akojanu-Ile Igbimọ Asofin Ọyọ, Gbenga Oyekọla Da’ba Pe O Se Pataki Lati rọ Awọn Ijọba Ibilẹ L’agbara Lori ọna Ẹsẹ Kuku Ati Igberiko
NEWS

Akojanu-Ile Igbimọ Asofin Ọyọ, Gbenga Oyekọla Da’ba Pe O Se Pataki Lati rọ Awọn Ijọba Ibilẹ L’agbara Lori ọna Ẹsẹ Kuku Ati Igberiko

Opeyemi RasheedBy Opeyemi RasheedMarch 22, 2024No Comments4 Mins Read
WhatsApp Facebook Twitter
Share
Facebook Twitter LinkedIn Pinterest Email

Alakojanu-Ile Igbimọ Asofin Ipinlẹ Ọyọ, ti o n soju Ijoba Ibilẹ Atiba, Asofin Gbenga Joseph Oyekọla ti Da’ba Ofin pe, o se pataki lati rọ awọn Ijọba Ibilẹ L’agbara lati pari sise atunse awọn oju opopona ni ẹsẹ kuku ati ọna Igberiko ni agbegbe koowa won ni Ipinlẹ Ọyọ.

Nigba to n sagbekale aba ohun, ni Ile Igbimọ Asofin Ipinle Ọyọ Lana, Asofin Gbenga Oyekọla Woye àwọn ipò tí kò bá ojumu tí awọn òpópóna ẹsẹkūku ati igberiko wá loni, bí ótile jẹ pé oriyin to sí ijọba Ipinlẹ Ọyọ lábẹ idarí ọlọlajulọ Onímọ Ẹrọ Seyi Mákindé, lórí idawọlé àti àseyọri awọn opopóna ijoba ipinle, Sugbọn ó se pataki kí á woye awọn òpopónà tí a ó tọ kí á tó de orí àwọn ọnà tí ljọba Ipinle se wọn yi.

Adari ile, ẹyin ẹlẹgbẹmi, lara ojúse ljọba Ibilẹ gẹgẹ bii ljọba tí o súnmọ ara ilu julọ ní láti pèsè àti síse atúnse awon opopona ẹsẹkuku ati īgberiko.

Eléyi wa ni ibámu pẹlú Iwé Ófin Orilèède yí ní ipín kẹrin (fourth schedule) ní abala ‘P’ sí nóm bà kìní (1)(f) eýi tí ó pa ljọba Ibilẹ làse láti la opopóna ati sisę amójutó àwọn òpópóna tí ó wa ni ikawọ wọn (Construction and Maintenance of Roads).

Ẹwẹ, Oyekọla túbọ woye pé kika wo ro awon Ijọba ibilẹ si ojuse won wonyi wa lára ohun tí o se okufa ijakulẹ tàbí owọn gogo oúnjẹ eyí tí ará ilú ńkojú lọwọlọwọ, ẹyin ẹlẹgbẹmi akóbá ńlá ni ipò gárí gádá tí àwọn òpópóna igberiko wa nse fún ijageere ọkọ láti kó awọn ikóore láti oko wá sí ọja nibití ara ilú yío ti rí rà, ìwọnba tí ó ba jaja de ọja ni won yio gbówó geege gun lóri látări wíwón tí owó oko láti kó ère oko dé oja gbé lórí gege. Eyi si ndakun inira tí ará ilu ńkojú lásiko ipènijà ọrọ ajé tí a wà yĩ.

O tun Kiyesi pé, ijọba Ibilẹ ni isakóso tí ó kangun sí ará ilú julọ, èyí tí awọn oludibo sì ní Iretí kíkún nínú rẹ pé yíò bu omi tútù sí ibi tí bata ti í ta wón ní ẹsẹ, pípọ ojúse tí ará ilú ńretí pé ljọba Ibilẹ yio gbájú mọ lố tì wà ní ipò ọmọ orukan, eyí tí kò sí ẹni tó rí gẹgẹ bí ojú se wọn làti samójúto rẹ.

Akojanu-Ile Igbimọ Asofin, tubọ kiyesi pe siwaju asiko yí awon isé takun takun ní ẹsẹkuku tí awon ljọba Ibilẹ má nse ni kiïse fi ọwọ rọ sẹyìn nínú síse odiwon tabi igbelewon isakoso kan si omíran. Siwaju asiko yi, ọpọlọpọ awọn opopoña to wa ni ikawo ljoba Ibilẹ ni ó ma nrí atunse lore koore páapá julọ awon oju opopona igberiko.

“Eyi si je ona kan pato ti ljoba ngba lati sọ awon to ngbe ni igberiko ati awon to wa ni igboro pọ fun idokowo ati irufẹ awon ohun amú ayé derọ míran”.

Akojanu-Ile túbọ Gbarata pe, lái se pé ljọba Ipinle Ọyo lábẹ Onímọ Ẹrọ Seýi Mákindé rọ awon ljọba ībilẹ lágbára láti parí síse atunse awon opopona esekuku ati ní pataki julọ awọn opopona ti o so igberiko mó igboro, paapa bí asiko ojo se fi ese lelẹ bayi, ńse ni awon ojú opopona yi yiò má bajẹ si tí yio sì ma lekun isoro igbokegbodo abi lilọ bibọ oko tí o sile se akobá ńlá fuń kiko ere oko wasi ọja bákanná ni o le yọrí si ọwọn gogo ounjẹ.

Lẹyin eyi ni Alakojanu-Ile ati Igbimọ Asofin Ipinlẹ Ọyọ pinu lati ro Ẹka Alásẹ ljọba pe;

Ẹka Alasẹ nipasë llé Isẹ ljọba to nri sí ọrọ ljọba Ibilẹ ati Oye Jijẹ (Ministry of Local Government and Chieftaincy Matters) ní Ipinlẹ Ọyọ láti seto ríró Ijọba Ibilẹ lagbara isuna owo latii pari sise atúnse awon opopona ẹsẹkuku papa julọ awon opopona igberiko.

Bakanna lati se igbesẹ bi lila ati sise atunse opopona igberiko yió se wá nínu awọn èto to le waju nínu Aba Isuna awon ljọba Ibilẹ, fun odun yí (2024).

Ki Igbimo lle tó o wà fun ọrọ ljọba Ibilẹ, Oye Jíjẹ ati Idalọla Ipinlẹ (Committee On Local Government, Chieftaincy Matters and State Honours) fikun-lukun pẹlú ilé isẹ to ri si ọrọ ljọba Ibilẹ ati Oye Jije (Ministry of Local Government And Chieftaincy Matters) lori síse amuse ifẹnuko llé pe ki Eka Alásẹ o rọ awon ljọba Ibilẹ lagbara ki won o le pari sise atunse awon opopóna ẹsẹkuku ati igberiko.

Akojanu-Ile Igbimo Asofin Ati Igberiko wa Da'ba Pe O Se Pataki Gbenga Joseph Oyekola Heritage Echo News Heritageecho.com Ijoba Ibile ese Kuku Lati ro Awon Ijoba Ibile L'agbara Ni Ipinlệ Òyó
Share. WhatsApp Facebook Twitter
Opeyemi Rasheed
  • Website

Related Posts

Ib’North Bye-Election: Gbolarumi Congratulates Folajimi Oyekunle On Election victory

August 22, 2025

Watch: Makinde’s Administration Drives Oyo PTS Major Transformation to International Standard [VIDEO]

August 22, 2025

PHOTOS: Fire Engulfs Residential Building In Iseyin

August 22, 2025

Ido Council Boss Prays for Successful Reign of Olubadan-Elect

August 22, 2025
Add A Comment
Leave A Reply Cancel Reply

Recent Posts

  • Ib’North Bye-Election: Gbolarumi Congratulates Folajimi Oyekunle On Election victory
  • Watch: Makinde’s Administration Drives Oyo PTS Major Transformation to International Standard [VIDEO]
  • PHOTOS: Fire Engulfs Residential Building In Iseyin
  • Ido Council Boss Prays for Successful Reign of Olubadan-Elect
  • Ibadan LG Chairmen Pay Homage to Olubadan-Designate, Oba Rasheed Ladoja

Recent Comments

No comments to show.
Editors Picks
Top Reviews
Advertisement
Demo
Heritage Echo
Facebook X (Twitter) Instagram WhatsApp
  • HOME
  • ABOUT US
  • CONTACT US
© 2025 Heritage Echo News. Designed by SPLASH ARTS CONTACT US ON 08059330901.

Type above and press Enter to search. Press Esc to cancel.